Upload
phamtram
View
234
Download
2
Embed Size (px)
Citation preview
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Oyèbámijí, Akeem Koláwọlé
Federal College of Education, Zaria 08035926490
Àsamo Yorùbá bo won ní ilé ni àá wò, kí á tó sọ ọmọ lórúkọ. Òwe yìí yóò máa toka sí onà tí ìran Yorùbá máa ń gbà ronú kí wọn tó dáwo le iṣe tàbí nǹkan kan láti ṣe tàbí ìwà kan láti hù. Yorùbá gege bí eyà kan tàbí oríle-èdè kan je aláròjinle, olùwádìí àti alákìyésìí. Lára ìwádìí àti àròjinle pelú àkíyèsí won ní pé kí Olódùmarè tó dá àwọn (ọmọ ènìyàn) ni ó ti koko dá àwon nǹkan kan sí àyíká wọn. Ìbéèrè ti won koko ń bi ara wọn ni pé kí ni èrèdí dídá tí Olódùmarè koko dá àwọn nǹkan wonyìí ṣaájú kí ó tó dà àwọn? Nínú àròjinle won nàá ni won tí ń wá ìdáhùn pé Olódùmarè dá àwọn nǹkan wonyìí fún ìlò àti àǹfààní ọmọnìyàn ni. Púpọ nínú àwọn nǹkan tí Olódùmarè dá sí àyíká edà bíi afefe, odò (omi), igbó kìjikìji, ewéko, òkè ńlánlá, àpáta, ẹranko ìgbẹ ati tilé, abbl ló je pé Olódùmarè dá wọn fún ìlò ọmọ edá ènìyàn. Nínú ìṣemí ayé ọmọ edá ènìyàn, igun pàtàkì ni Yorùbá fi oro àlàáfìá àti ìlera wọn sí. Irú ọwo wo ni àwọn ènìyàn fi mú oro ilera won? Oju wo ni won fi ń wo àwọn edá àyíká tí won kì í ṣe ènìyàn wonyìí? Ǹje àwọn ènìyàn àwùjọ mo pé bí a bá ń soro ìlera tó péye, ohun tí a ń wá lọ sí sókótó ń bẹ ní àpò sòkòtò wa bí? Pépà yìí tan ìmole sí orísìrísìí onà tí a le gbà ṣe àmúlò àwọn nǹkan tí Olódùmarè dà sí àyíká wà fún ìlera àti ìsemí ayé tó péye.
86
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Ìfáárà: Kin ni Àyíká
Àyíká je gbogbo aayé tí ó súnmo tàbí tí ó wà ní ìtòsí ibi tí
ènìyàn ń gbé. Àwọn nǹkan àwòmo àyíká lè je ohun tí a lè fojú rí
tàbí fọwo kàn. Wọn tún lè je ohun àfinúrò tí ó ńii ṣe pelú
ìgbàgbo ẹnìkan pé àwọn emí tàbí edá kan tí a kò lè fojú rí tàbí
fọwo kàn wà ní àyíká wa. Yorùbá bo won ní ìlera lọro. Yorùbá a
tún máa sọ pé àlàáfìá ni olúborí oore tí Ọlorun Olódùmarè le ṣe
fún edá. Pé ẹni tí ó bá ti ní àlàáfìà, ohun gbogbo ló ní. Bí ó tile
je pé oríṣìíríṣìí onà ni a lè gbé oro nípa ìlera edá gbà, ìlera
ènìyàn tó níi ṣe pelú àwòmo àyíká ní pépà yìí fe fúnká mo.
Àfojúsùn pépà yìí ni pé nígbà tí ènìyàn bá ní àlàáfìà tó péye
nípa ṣíṣe àmúlò àwọn ohun tí Olódùmarè dá sí àyíká rẹ, tí àyíká
náà si tòrò nini, edá ènìyàn yóò lè sin Olódùmarè nípa fífi ọpe
fún un gege bí Ọba Adedàá Asedá àti Olùpèsè.
Irú ìwà yìí ni yóò jẹ kí inú Olódùmarè máa dùn kí inú
edá gbogbo náà si máa dùn pelú. Olódùmarè ni ó fi ènìyàn ṣe
olórí gbogbo àwọn edá tó dá (Bíbélì, Kùránì àti Ẹsẹ-ifá) toka sí
èyí, síbe ètò owó nílé lókò lódò ni àtìrandíran Yorùbá ti ń lo
saájú kí àwọn èèbó tó gòkè odò wá. Ìtumo owó nílé lóko lódò ni
pé àwọn edá yòókù yàto si ènìyàn ti Olódùmarè dá wonyìí ní
àwọn ètò tàbí àfojúsùn tí won ń retí lodo ènìyàn, bí ó tile je pé a
dá wọn láti le è wúlò fún ènìyàn nàà ni.
Gege bi àkòrí iṣe yìí, ‘ètò ìlera ajẹmo àyíká: àyewò
ìbáṣepo láàrín ènìyàn àti edá abemí mìíràn,’ oríṣìírìṣìí onà tí
ènìyàn le gbà ṣe àmúló àyíká tàbí lo ànfààní àwọn nǹkan tí
Olódùmarè dà sí àyíká re lonà tó to fún ìlera ni a ó máa fúnká
mo nínú pépà yìí. Kí iṣe àpilekọ yìí lè ní òòrìn, a ó tọpa re wọ
inú ìgbàgbo, esìn, èrò ìjìnle àti báyéṣerí àwọn Yorùbá. Díe nínú
87
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
àwọn ohun tí Olódùmarè dá tí a ó máa ṣàlàyé gege bí wọn ṣe
wúlò fún ìlera ọmọ edá ènìyàn ní àyíká wọn ni afefe, odò/omi,
igi/ewéko, àpáta/òkè àti ẹranko lóríṣìíríṣìí.
Láti rí èyí ṣe, a ó ṣe àyewò ohun tí àwọn onímo ti sọ nípa
àyíká àti ìwòye àwọn àjọ kan tàbí èkejì tí iṣe wọn jẹ mo ètò ìlera
ajẹmo àyíká. A ó wá parí atótónu wa sí ìjíròrò lórí ìlera ajẹmo
àyíká pelú àwòmo àwọn nǹkan tí Olódùmarè dá sí àyíká ọmọ
edá ènìyàn.
Tíorì Àmúlò
Tíorì lítíréso tí a ó máa ṣe àmúlò nínú iṣe yìí ni tíorì lámèéto
ajẹmo àyíká (eco-criticism). Tíorì yìí ni a ó fi ṣe àtegùn láti ṣe
àtúpale àkòrí iṣe wa, ìlera ajẹmo àyíká. Gege bí Ọpefèyítìmí
(1997) ṣe pìtàn re, ìpàdé àpérò ẹgbe àwọn onímo lítíréso níle
Geésì (Western Literature Association) ní ọdún 1970 ni ó bí
Tíorì yìí. Ibi tí won fi ẹnu oro jóná sí níbi ìpàdé náà ni pé kí
àwọn òǹkowé máa gbé iṣe wọn kale lonà tí yóò fi ḿaa ṣe àfihàn
pàtàkì àwọn nǹkan tí Olódùmarè dá sí àwùjọ ènìyàn. Oro ẹnu
Dobie ti Ọpéfèyítìmí (1997) ṣe àgbékale re ṣe é fi ìka to níbí:
They are interesting in examing the relationship of literature and NATURE as a way to renew a reader’s awareness of the non-human world and his/her responsibilities to sustain it. Sharing the fundamental premise that all things are interrelated, they are actively concerned about the impact of human actions on the environment (1997:239). Ohun tí ó mú wọn lokàn ní àyewò ìbáṣepo lítíréso àti àwon edá abemí láti lè je kí àwọn òǹkàwé mọ
88
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
iṣe wọn gege bí olùtojú àwọn nǹkan tí Olódùmarè dá sí àyíká wọn yàto sí ènìyàn. Pẹlú èrò àti ìgbàgbo pé gbogbo nǹkan tí Olódùmarè dá ni ó fi ara kọ ara wọn fún ànfààní kan tàbí èkejì sí ara wọn, ohun tí ó kàn won gbongbon ni ìsesí àwọn ènìyàn lórí àwọn edá tí kì í ṣe ènìyàn ní àyíká.
Èrò Ìsolá (2010) lórí lámeeto ajẹmo àyíká náà ṣe é yewò. Ó gbé
erí kale lórí bí ó ṣe ṣe pàtàkì láti máa tojú àwọn nǹkan tí
Olódùmarè dá sí àyíká wa:
Eco-criticism goes beyond the merely physical; it extends to the emotional and philosophical. When properly nurtured and preserved, the geographical eco-criticism provides food and atmospheric conditions that satisfy the physical and health needs of the people (2010:103-104) Lámeeto ajẹmo àyíká gbòòrò ju ohun tí a lè foju rí ní àyíká nìkan lọ. Ó níí ṣe pelú ìjìnle èrò àti ìmolára edá. Tí a bá tojú àyíká wa bí ó ti to àti bí ó ti yẹ, oúnjẹ yóò sùn wá bo, bee ni àlàáfíà gidi yóò tó wa lowo.
Yàto si àǹfààní kan tàbí èkejì tí èèyàn lè rí gbà nípa títojú àyíká
re, Ìṣolá (2010) ṣe kìlokìlo nípa ṣíṣe àwọn edá àyíká wa bí kò ti
yẹ. Ẹ gbó ohun tí ó wí:
When you cut a single tree in the forest, you destroyed the source of food and abode of some animals, birds and thousands of insects, some of which will perish in their attempt to find new homes. When a species of plants disappears, the human race loses not only animal feed but also
89
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
possible cure for a number of diseases (2010:103-104) Bí a bá gé igi kan nínú igbó, ilé àwọn ẹranko kan, àti ẹgbẹegberún ẹyẹ àti kòkòrò àti onà oúnjẹ wọn ni a ti bàje yẹn. Púpo nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ wonyìí ni yóò kú níbi tí won bá ti ń làkàkà ĺati wá ilé tuntun mìíràn àti oúnjẹ. Tí oríṣìí ewé kan bá pare, kìí ṣe pé onà oúnjẹ òòjo àwọn ẹranko kan tán nìkan, ó ṣeé ṣe kí á ti pàdánù ohun tí ó wà fún àwárúnsàn lóríṣìíríṣìí.
Kókó ohun tí Ìsolá (2010) ń sọ níbí ni pé, bí a bá ń soro ìtojú
àyíká, ọmọ ènìyàn ní láti ṣe pelepele pelú àwọn nǹkan tí
Olódùmarè dá sí àyíká wọn. Ohun tí ó tún ṣe pàtàkì sí wa nínú
iṣe yìí ni àkíyèsí Ọpefèyítìmí (1997) pelú bí àwọn èèyàn kan kò
ṣe gba odò/omi láàyè láti sàn bí Olódùmarè ti dá a àti bí oun
pàápàá ṣe ń fe ní agbègbè eko. Oro re nìyí:
Ẹ wo àwọn tó rale kolé sínú irà àti ojú omi lékòó. Tí won ń kó yanrìn dí àwon omi àti irà náà pelú mílíonù àìmọye náírà. Àwọn onímo sáyensi sọ pé’ water finds its own level’, ìyẹn ní pé lojo iwájú, omi tí ẹ rò pé ẹ ti kó yeepe dí lé selerú sínú kò sì fa ilé ríru fún àromọdomọ onílé (o.i48).
Oro nípa bí wíwá epo robì àti èéfín gáàsì ṣe ń ba àyíká je ní
agbègbè Niger Delta ni ó múmú láyà Feghabo (2014). Feghabo
ṣàlàyé pé àwọn ekánsíle epo robì àti èéfín gáàsì to máa ń dì
kùrukùru sí ojú orun ní agbègbè náà ti ba gbogbo àyíká ibe je.
Feghabo fi kún oro re pé ọṣe tí àwọn ekánsíle epo robì àti èéfín
gáàsì yìí ń ṣe lágbègbè náà kò kéré. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àyíká ni
90
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
ó ti di asále, gbogbo àwọn ẹranko ìgbe ni won sì ti sálọ sí ibi tó
jìnnà rere.
Nígbà tí ó ń jábo ìwádìí re, Oyèláràn (2011) ṣàlàyé pe
yàto sí pé àwọn ará ìlú Bámijòkó ní ìpínle Ògùn àti Òkómù ní
ìpínle Edó ní àyíká won gege bí onà láti rí oúnjẹ òòjo, won tún
rí àyíká wọn gege bí orísun ìgbàgbo wọn. Oyèláràn fi kún
atótónu re pé àwọn ará ìlú wonyìí rí àyíká wọn (inú igbó
kìjikìji) bíi ilé ìbọ òrìṣà níbi tí ìmolára tiwọn pelú ti àwọn òrìṣà
wonyìí kò ti ṣeé já tàbí pín. Èyí ni pé inú igbó tí ó wà ní àyíká
yìí ni ó dàbí ilé fún àwọn ìbọ wọn gbogbo. Èyí náà ni ó sì fa
òfin tí won fi léle ni àwọn ìlú wonyí pé ẹnikeni kò gbọdo gé igi
kan, ṣe ọdẹ nínú igbó yìí tàbí dáná sun igbó náà bèlèntàsé ríra
tàbí títà láti fi ko ilé (Oyèláràn o.i 15).
Ìwádìí Oyèláràn, (2011) fere ṣe déédéé pelú ti Bunza,
(2007). Bunza sàlàyé pé ní agbègbè Zúrú ní gúúsù ìla òòrùn
oríle-èdè Nigeria, ojúbọ kan wà níbe tí wọn ń pè ní Grimace.
Bunza fi kún àlàyé re pé ẹnikeni kò gbọdo ṣe ọdẹ ní agbègbè
náà. Nítorí pé ẹnikeni tó bá pa ooni tó je òrìṣà tí wọn ń bọ, tó sì
dúró bíi Ọlorun agbègbè náà yóò kú pelú ooni náà ni.
A lérò pé irú ètò báyìí ni Santangelo (2007) ri tí ó fi sọ pé
‘that the eco-critics insist that in literary studies, non-human
nature must be treated as having an existence and value’. Èyí ni
pé kí lámeeto lítíréso ajẹmo àyíká tàbí oníṣe onà ajẹmo àyíká
máa fi iṣe rẹ ṣe àfihàn pàtàkì àwọn edá àyíká ti won kì í ṣe
ènìyàn wonyìí pelú bí ó ṣe je pé wọn ni ìwà, emí àti ànfààní tàbí
ìwúlò kan.
Slaymaker (2007) pè fún ṣíṣe déédé láàrin ènìyàn àti
àwọn edá ti won kì í ṣe ènìyàn ní àyíká. Oro re lọ báyìí:
91
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Environmental justice as a global paradigm will be used in the world market place when decisions are made about production consumption of resources and pollution caused by modernization, industriliazation and population growth. Dédé àjẹmo àyíká àti àwọn ènìyàn ibe gege bí ọpá òdiwon gbogbogboo ni a ó máa ló ni ọjà àgbáyé nígbà ti ìjíròrò tàbí ìfoŕikoŕi bá ń wáyé nípa ìpèsè àwọn nǹkan kan, lílò àwọn nǹkan tí Olódùmarè fi ta àwùjọ lóre àti àwọn nǹkan tí ó ń bá àlàáfìà ìlú je, ti igbe ayé otun, ìdókòwò, àti bí èèyàn ṣe po tó dá síle.
Oro Oyèláràn (2011) ni a ó fi ka atótónu àwọn onímo àjẹmo
àyíká níle. Oyèláràn tan ìmole sí ibi tí ó jọ pè òkùnkùn fe wá
nínú oro Slaymaker òkè yìí. Ohun tí Oyèláràn sọ ni pé
we do not believe in an undesirable sophiscated modernization and inducstrilization, as they do more harm than good… That many highly significant environmental changes were and are being achieved by non-industrial societies like Nigeria. Àwa kò ní ìgbàgbo nínú ìgbé ayé otun yeye àti ìdókowò ìrégbè nítorí pé ọṣe tí won ń ṣe jù dáadáa wọn lọ. Pé àìmọye àyípadà tó ni ìtumo ni ó ti ń dé bá agbègbè tàbí àyíká ti wọn kò dágbálé ètò olókoowò ńláńlá bíi ti orílẹ-èdè Nàìjìríà tí ó sì tún ń dé bá wọn lowolowo.
92
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Ohun tí gbogbo àwọn agbátẹrù tàbí lámèèto tíorì àjẹmo àyiká ń
tẹnumo ni pé bí Olódùmarè ṣe dá edá ènìyàn pelú iṣe tàbí ìwúlò
kan tàbí òmíràn láyé láti ṣe fún Olódùmarè, náà ni Olódùnmarè
dá àwọn edá mìíràn ti wọn kì í ṣe ènìyàn fún ànfààní kan tàbí
èkejì. Kókó atótónu àwọn onímo lámeeto àjẹmo àyíká ni pé kí
àwa ènìyàn àwùjọ rí àwọn edá àyíká wà gege bí ohun tó ní ìwà,
emí, ìmolára, àti ànfààní kan tàbí òmíràn. Láti tọpinpin irú
ànfàní tí a menu bà yìí, èrò àwọn onímo ni pé gígé igi lule láìní
ìdí kan pàkàkì kò dára. Sísán tàbí gígé àwọn ewéko àyíká dànù
kò sunwon. Bee náà ni pípa àwọn ẹranko ilé àti ti ìgbe ni
ìpakúpa kò tonà. Dídí onà mo odò/omi láti sàn kù díe káàtó.
Dídána sun igbó orò tàbí ojúbọ òrìṣà kò bójúmu. Pé bí a bá ń gé
igi nígbó, kí a máa fi oro ro ara wa wò.
Ìgbàgbo Yorùbá nínú Olódùmarè nípa àwọn Edá Àyíká
Yorùbá gbàgbo pé kì í ṣe edá ènìyàn nìkan ni ó ní ìwà, emí,
ìmolára àti ànfààní kan tàbí èkejì. Bí ènìyàn ọmọ adáríhunrun ṣe
ní ẹmí àti ìmolára nǹkan bee ni àwọn edá tí wọn kì í ṣe ènìyàn
bí i igi/ewéko, ẹranko (tilé àti tìgbe), ẹja inú omi, òkè/àpáta àti
odò/omi àti ẹyẹ ojú orun náà ni. Yorùbá tún gbàgbo pé àwọn
ohun ẹlemìí kan tí wọn kì í ṣe ènìyàn sí wa tí ó je pé a jọ ń gbé
ní àyíká ni. Àwọn ohun ẹlemìí wonyìí le je obọ, iwin àti
àlùjonnnú oríṣìíríṣìí. Lóòóto ni pé a kò rí wọn, ṣùgbon Yorùbá
gbàgbo pé wọn ń bẹ àti pé wọn ní emí àti irúfe agbára kan,
(Abimbola, 1975, 1976; Ìsolá, 1992, 2010).
Yorùbá gbàgbo pé oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbe ló wà àti pé
àwọn ẹranko mìíràn ní agbára láti yí padà di ohun tí wọn bá fe.
93
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Àgbonrín àti ẹfon a máa yíra padà di ìnájá, òǹtajà tàbí òǹràjà
nínú ọjà ọmọ ènìyàn, (Olayemi, 1975; Obed, 2001; Ìsolá, 2010).
Yorùbá tún gbàgbo pé àwọn iginìyán wà. Èyí ni pé àwọn igi kan
wà ti wọn ní agbára àìrí kan. Pé àwọn emí alágbára kan wà nínú
igi ti Yorùbá ń pè ní oro, (Bamgbose, 1974; Ìsolá, 1992). Yorùbá
gbà pé kì í ṣe ara ènìyàn nìkan loore wà, ‘igi tó bá ṣeni lóore làá
wárí fún’, (Ajíbádé àti Rájí, 2011). Lára ìgbàgbo Yorùbá tún ni
pé emí àìrí le wà nínú afefe, òkè tàbí apáta. Gbogbo odò ni ó ni
alákòóso wọn àti pé àwọn edá inú odò náà ni àwọn agbára àìrí
kan bee náà ni wọn ní ìmolára nǹkan.
Esìn Yorùbá
Gege bí a ṣe feeke lù ú ní ìbere, esìn Yorùbá rọ kiri ká ìgbàgbo
wọn nínú Olódùmarè pelú oríṣìíríṣìí orúkọ ti wọn fún un láti ṣe
àpèjúwe re. Gbogbo àwọn nǹkan tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó ba
ni lerù tàbí tí ìwà wọn tojúsúni tàbi koni lóminú ni Yorùbá gbà
pé ó yẹ kí àwọn wáárí fun. Ìdí nìyí tí wọn fi máa ń kóbì bọ òkè,
odò, igi ńláńlá, abbl. Bíbọ ti Yorùbá ń bọ àwọn nǹkan tí a
dárúkọ wonyìí kò ṣeyìn ìgbàgbo wọn pé agbára àwọn nǹkan
wonyí po débi pé won lè fi aburú kan tàbí èkejì kan ènìyàn. Pé
bí a bá lè máa rọ àwọn emí àìrí wonyí, láti ara bíbọ won nípa
fífún wọn ni ohun tí a mo pé wọn feràn láti máa je, won kò ni le
fi aburú kankan kan ènìyàn. Lára emí àìrí ti Yorùbá gbàgbo pé
won ní ìkápá lórí edá ènìyàn ní òkú orun. Ìpèdè Yorùbá kan ní
“ìgbìn làá lù fún òósálá kó tó máa jó, ẹkún làá sun fún òkú orun
kí wọn ó tó máa gbéni”. Fífún òkú orun ní ohun tí wọn ń fe ni ó
fara jọ ekùn tí a sọ lókè yìí. Onà kan pàtàkì ti Yorùbá fi ń
sàponlé òkú orun ni nípa gbígbé egúngún, òkú pípè, àti sísun
94
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
ìrèmojé, (Babayẹmí, 1980; Àjùwon, 1982; Àmoó, 1982;
Fátókun, 2005). Lára ohun tí ó tún ṣe àfihàn esìn níle Yorùbá ni
bíbọ òrìṣà. Oríṣìírìṣìí ni òrìṣà ti Yorùbá máa ń bọ (Olúpònnà,
2011; Ìdòwú, 1996). Lára àwọn irú òrìṣà bee ni òrìṣà tí wọn fi tẹ
ìlú kan dó tàbí àwọn àkọni tí wọn bínú wọle tàbí tí wọn di igi
tàbí òkè tàbí àpáta. Díẹ lára òrìṣà tàbí ìbọ níle Yorùbá ni Òòṣálá,
Ògún, Ṣàngó, Ọya, Oṣun, Òrìṣà oko, Èṣù abbl, (Dáramolá àti
Jeje 1967).
Lára ohun tí Yorùbá máa ń bowo fún tí ó tún lapa nínú
esìn wọn ní pepefúrú ti wọn máa ń ṣe fún àwọn àje àti oṣó tí
wọn gbàgbo pé àwọn ni Olódùmarè kó òkun ayé lé lowo,
(Ilésanmí, 2014). Bí ó tile je pé ènìyan lásán kò lè mo won,
agbára wọn po àti wí pé ó fere ma sí àrà ti wọn kò lè fi ènìyan
dá. Gbogbo onà ti Yorùbá gbé ìsìn/esìn wọn ká ló níí ṣe pelú
àkíyèsí àti ìbowo fún àyíká wọn. Gbogbo ohun ti Olódùmaré dà
sí àyíká tí Yorùbá ti bá ara re ni ó ń ṣe wọn ní kàyèéfì, tí ó ń
derù ba won. Èrò àti ìgbàgbo Yorùbá ni pé àwọn edá tí wọn kì í
ṣe ènìyàn wonyí ṣùgbon ti agbára wọn po yẹ ní bíbo kí àlàáfìà ó
le jọba ní àyíká àti àwùjọ lápapo.
Èrò báyéṣerí Yorùbá nípa Àyíká
Leyìn ìwádìí ìjìnle àti opolọpo àkíyèsí, Yorùbá wòye pé kì í ṣe
pé gbogbo nǹkan tí Olódùmarè dá dára nìkan ko, àwọn náà ni
ìwà, emí àti ìmolára nǹkan bíi ti ènìyàn, ọmọ adáríhunrun. Won
ní agbára àìrí kan, wọn sì kún fún opolọpo àǹfààní fún olùgbé
àyíká tí wo n bá wà.
95
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Ìlera Ajẹmo Àyíká: Àyewò ìbáṣepo láàrin ènìyàn àti àwọn
e dá abemí mìíràn
Lóòóto ni pé àwọn onímo kan gbé ìwádìí wọn jáde pé fífe ti aye
ń fẹjú lójoójúmo àti pípo ti ènìyàn ń po síi lórí ile ló ń pagidínà
àlàáfíà àwọn edá abemí tí won yàto sí ènìyàn, ṣùgbon le nu
looloo yìí àwọn onímo mìíràn ti gbé oriṣìíriṣí erí jáde pé kì í ṣe
pípo tí ènìyàn po ló ń pagidínà àlàáfíà àwùjọ bi ko ṣe ètò ìṣèlú
tó ro mo ìdókòwò alàdàáńlá (Fearnside, 1993; Hultric et al,
2002; Armitage, 2002; Glaser et al, 2003; Hultric, 2005). Díe
lára irú ìdókòwò tí won sọ pé ó ń pagidínà àlàáfíà àwọn edá
abemí wonyí ni kíkó ẹja lódò lopo yanturu fún títà; àti pípale
rẹpẹtẹ fún agbo mààlúù; láti máa sìn fún títà.
Ìwé ìròyìn Daily Trust ọjo Móńdè, 31-08-2015 gbé
ìròyìn kan jáde tó dálé orí ìlera ajẹmo àyíká. Ìwé ìròyìn náà ní
ìwádìí ìjìnle ti fi ìdí re múle pé àìmọye kòkòrò kéékèèké tí wọn
kò ṣeé fi ojú rí, ni won máa ń ba eruku kowoo rìn. Kókó ohun tí
ìròyìn náà tẹnumo ni pé àwọn kòkòrò tí won máa ń ba eruku
kowoo rín wonyìí máa ń ṣe àkóbá fún ìlera ènìyàn ni.
Opolọpo ariwo gèè tí ó ń ti àwọn ilé ìjosìn, ilé ìtura àti ilé
ìgbafe wà àti bí won ṣe ń pagidínà àlàáfìà ará ìlú ni oro olóòtú
ìwé ìròyìn Daily Trust ọjo Ẹtì, 28-08-2015 dálé lórí. Ìwé ìròyìn
náà ṣàlàyé pé o ti di bárakú fún àwọn onílé ìtura àti àwọn tó ń ta
oúnjẹ àti ọtí láti máa yín rekoodù orin wọn sókè lalaala láìnáání
ọse tí irú ìhùwàsí bee ń se ní àyíká. Ìwé ìròyìn náà tún fi kún
àlàyé re pé ariwo tí àwọn olùjosìn mùsùlùmí àti àwọn ọmọleyìn
Jésù máa ń pa ní òru níbi ìwàásù àti ìso òru ń kóbá àlàáfìà
lápapo.
96
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Kókó ohun tí ìwé ìròyìn yìí ń wí ni pé bí a bá ń wá àlàáfìà ní
àyíká, ìwon ni nǹkan dùn mọ nípa àpojù ariwo ní àyíká.
Lórí oro ìlera àjẹmo àyíká ewe, àgbékale ètò ìṣàtúnṣe
ìjọba àpapo, Ọlogbondàà-arónilágbára Àjẹmo Ọroajé àti
Ìdàgbàsókè (NEEDS, 2005) pè fún àkíyèsí. Kò sí kí oro àyíká
má kàn NEEDS tele, níwon ìgbà tó je pé àfojúsùn re ni
ọgbondáá oro ajé àti ìdàgbàsókè àwùjọ tàbí àyíká. Kókó iṣe
merin otooto ni àfojúsùn NEEDS, (2005). Iṣe merin tó fe máa ṣe
ní eka ìlera àwùjọ ni ṣíṣe àwárí onà ti àwọn nǹkan egbin àti ìdotí
ṣe ń wáyé ní àyíká àti bí a ṣe lè kó wọn kúrò níle. Nǹkan kejì ni
èyí tí ó níi ṣe pelú ìlàkàkà lórí bi gbogbo àyíká wa kò ṣe ni di
aṣále. NEEDS, (2005) ṣàlàyé pe ṣaájú àsìkò yìí, àyíká wa ní
Nìàjíríà kún fún àwọn igbó kìjikìji ṣùgbon lenu looloọ yìí aṣále
ti fe gbórí lowo igbó kìjikìji. Ohun kẹta tí ó tún fe fara pe èkejì
ni NEEDS pè ní ṣíṣe àwon ẹranko kan lojo sí àwọn ààyè kan, tó
dára, tó tejú, tí yóò si ṣe déédéé pelú ibi tí àwọn ẹranko náà yóò
ní ìfe sí. Èrò NEEDS lórí èyí ní pé, bí a bá tojú àwọn ẹranko
ìgbe tí wọn ṣe pàtàkì wonyìí, tí a ṣe won lojo sí ibi tí àwọn
ènìyàn ti le máa wá wò won yóò ṣe ànfààní fún àyíkà àti oríle-
èdè lápapo. Ètò kẹrin tí NEEDS gbé kale ni ó pè ní gbígbógun ti
àwọn nǹkan tí ó lè ba àlàáfìà àyíká je. NEEDS ni ó yẹ kí òfin
oríle èdè wa lágbára láti lè fòpin sí oro àwọn nǹkan tí ó ń
pagidínà àlàáfìà ìlú. NEEDS, (2005) fi kún àlàyé re pé lára
nǹkan tí ó ń dín àlàáfìà ìlú kù ni ekànsíle epo robì àti èéfín gáàsì
tí ó máa ń di kùrukùru sí ojú orun bíi síṣú òjò.
Bí a bá wo kókó nǹkan merin tí NEEDS gbé kale yìí, a ó kíyèsí
pé gbogbo re náà ló jẹ mo ìlera àti àlàáfìà àyíká, ọmọ edá ènìyàn
àti àwọn edá tí won kì í ṣe ènìyàn. Màjàdùnmí, màjàdunra-ẹni ni
97
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
oro títojú àyíká je nítorí pé bí ìgbà tí ènìyàn ń tojú ara re náà ni.
Ní bàyìí, ẹ je kí á wo àwọn onà ti àwọn edá àyíká lè gbà wúlò
fún ìlera ọmọ edá ènìyàn lápapo.
Ìwúlò afefe fún ìlera edá ènìyàn
Mímí sínú àti sóde ni ó ya àlààyè ènìyàn soto kúrò láàrin àwọn
òkú. Bí ènìyàn kò ba ti lè mí mo, ó ti kú nìyẹn. Ohun ti
Wilkinson (2011) sọ nipa ìbáṣepo ènìyàn àti àwon edá abemí
mìíràn ni pe
The flora of the earth produces the oxygen that is breathed by the fauna and in turn the fauna exhale the carbon-dioxide that the flora need to live and that humans cannot live without either. Afefe tàbí èémí ti àwọn igi oko àti ewéko ìgbe ń mí síta tí a pè ni èémí àmísínú ni àwọn ẹranko ìgbe n mi sínú fún ìsemí àti àlàáfíà wọn, nígbà ti ó si tún je pé èémí tàbí afefe tí ó ń jade lára àwọn ẹranko ìgbe wonyìí ti a pe ni èémí àmísóde naa ni àwọn igi àti ewéko ìgbe nílò fún ìsemí àti àlàáfíà ti wọn, àti pe irúfe afefe tàbí èémí oríṣìí méjèèjì wonyìí ni ó wúlò fún ìsemí ọmọ edá ènìyàn.
Wilkinson (2011) wa fi èrò rẹ gúnle pé:
In fact human beings cannot breath unless both flora and fauna survive and thrive on the earth. The very air we breathe, and the food we eat, the medicine that cures us, and the water that keeps us alive would not exist were it not for flora and fauna. All things in an ecosystem are interdependent. The existence of one specie may depend on the health of another.
98
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Lódodo, ènìyàn ko le ni ìsemí àlàáfíà bí kò ṣe pé àwọn edá abemí yòókù yàto sí ènìyàn bá wà dáadaa; èyi ni wíwà ní bí ó ṣe to àti bó ṣe yẹ lórí ile ayé. Afefe ti a ń mí sínú àti sóde, oúnjẹ ti a ń jẹ, egbòogi ti ó ń wò wá sàn, àti omi ti a ń mu ìbá má wáyé bí kò ṣe nípase àwọn nǹkan abemí wonyí. Gbogbo nǹkan ti Olódùmarè da ni wọn jọ gbára le ara wọn fún àǹfààní kan tàbí òmíràn. Ìsemí nnkan abemí kan le gbára le ìwà tàbí alaafia nǹkan abemí mìíràn.
Onà mìíràn pàtàkì tí a fi lè mú ìlò afefe ni òkúnkúndùn nípa
ìlera wa ni gbígbé ní àyíká tó gbààyè. Bí àpẹẹrẹ tí a bá ko ilé, ki
a fi ojú fèrèsè tí ó fe, ti afefe yóò fi máa rí ààyè dé odo wa bí a
bá wà nínú ilé wa. Lára ohun tí ó tún ṣe pàtàkì nínú oro afefe ni
ètò gbíngbin igi àti àwọn òdòdó aláràbarà sí àyíká wa. Àwọn igi
àti òdòdó olóòórùn dídùn wonyìí máa ń pèsè afefe àlàáfíà tí ó
wúlò fún ìgbáyégbádùn ọmọ ènìyàn àti àyíká lápapo.
Ìwúlò Odò/Omi ní Àyíká
Yàto si pé odò je ilé ẹja àti àwọn edá inú omi yòókù ti won
wúlò fún ènìyàn gege bí oúnjẹ, odò náà ni a ti máa ń rí omi ti a
ń lò ni oríṣìíríṣìí onà. Oro Yorùbá kan lọ báyìí pé ‘a kì í bómii
sotá, omi la bùwe, omi la bù mu’. A kò tún le sese máa sọ rírí
omi láwùjọ. Gege bí a ṣe sọ nínú ìfáárà wa, Yorùbá gbàgbo pé
àwọn odò ńlánlá ni emí àti irúfe agbára kan. Pé bi ènìyàn bá mo
ètò àti onà rẹ, àwọn odò wonyí lè ran edá lowo fún ìlera wọn.
Ìdí nìyí tí àwọn Yorùbá fi máa ń bọ odò ńláńlá àdúgbò wọn.
Won tún máa ń sọ ọmọ wọn ní orúkọ tó jẹ mo omi tàbí odò kan;
99
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Omítóògùn, Omilabú, abbl. Àpẹẹrẹ irú odò báyìí ni ti Oṣun
Òṣogbo tí wọn máa ń bọ lodọodún.
Ìwúlò Igbó Kìjikìji ní Àyíká
Bí a bá ń soro igbó kìjikìji tó je ara àwòmo àyíká Yorùbá, kò sí
àníàní pé igbó kìjikìji je ilé awọn igi ńláńlá àti àwọn ẹranko
ìgbe. Èyí nìkan ko, inú igbó kìjikìji ni a tún lè pè ní ilé àwọn
òrìṣà, pàápàá ìgbàle egúngún. Yàto sí pé àwọn igi ńláńlá kan bi
igi ìrókò, ogànwó, arère, omo, igi opẹ, abbl máa ń lale hù pelú
àṣẹ Olódùmarè, tí won sì wúlò fún ilé kíko àti oríṣìíríṣìí àǹfààní
mìíràn fún ọmọnìyàn, a tún le gbin igi owó bíi kòkó, robà, o pẹ,
ọsàn, abbl. Inú igbó tún je orísun onà oúnjẹ fún edá ènìyàn.
Àwọn ọdẹ a máa pa ẹran tı ó wúlò fún títà tàbí jíje. A le sán
igbó láti gbin àwọn ohun tenu ń jẹ kan sí àyíká wa.
Ìwúlò Òkè ní Àyíká
Òkè ńláńlá máa ń pèsè ààbò gege bí ibi ìsádi kúrò lowo otá
pàápàá lásìkò ogun tàbí ote kan. Yàto sí èyí, ohun tí a gbo ni pé
àwọn nǹkan àlùmoonì máa ń wà nínú àwọn òkè àti àpáta ńláńlá.
Ewe, Yorùbá tún gbàgbo pé àwọn emí alágbára kan máa ń fi inú
àpáta tàbí òkè ńláńlá ṣe ilé àti pé ènìyàn le wá ìrànlowo kan tàbí
òmíràn lọ sórí òkè kan. Bí a bá ní kí a fẹ oro òkè lójú, a ó kíyèsí
pé opolọpo àwọn ènìyàn ni won feràn làti máa lọ sí orí òké kan
tàbí òmíràn láti lọ gba àdúrà tàbí wá agbára kan. Igbàgbo irú
àwọn ènìyàn báyìí kò ṣe lórí pé irúfe agbára àìrí tàbí ìmísí
Olódùmarè máa ń gbé inú òkè ńláńlá. Ju gbogbo re lọ, afefe
àlàáfìà máa ń ti orí òkè ńláńlá wà, èyí tí ó wúlò fún ìlera ọmọ
edá ènìyàn.
100
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Ìlera ènìyàn àjẹmo Àyíká tí o ro mo tewétegbò
Adéoyè, (2005) ń ṣe àfihàn ìgbàgbo Yorùbá nípa oògùn ìbíle
Yorùbá nígbà tí o sọ pé ‘Ọlorun kò kọ aájò’. Adéoyè tesíwájú
láti sọ pé kíko ni a máa ń kó oògùn àti pé ẹni ti yóò bá ko oògùn
gbọdo je ẹni ti ó ní sùúrù àti ìfaradà nítorí pé ‘opolọpo ọdún ni
ekose ìṣègùn máa ń gbà kí onítohún tó le gbówo’. Ó wá pìtàn pé
ọkùnrin kan ńbẹ nígbà kan tí orúkọ re ń je Àágberí. Ó ní
ọkùnrin yìí rí ìdí egbòogi àti pé lodo re ni opolọpo adáhunṣe ti
kose ìṣègùn. Kókó inú oro Adéoyè ni pé, ọjo ti pe tí ìran Yorùbá
ti kọbíara sí ìlò tewétegbò fún ìlera wọn pelú erí pé wọn máa ń
ko ọ gege bí iṣe àṣelà ni.
Fádípe (1970) pín oògùn níle Yorùbá si, (1) awàrùnsàn,
mojèlé, àpèta/àfikàn, ajẹméèwo, èpè, oṣó àti àje àti oògùn
ajẹmesìn. Fádípe ṣàlàyé pé bí oògùn ṣe lè jẹ mo agbára emí àìrí
tàbí ohun ìkoko, bee nàá ni a rí oògùn tó jẹ mo àkójọpo egbòogi
tó fe lo ní ìlànà ìmo sáyensì. Èyí ni oògùn tí a lè fojú rí kí a sì ṣe
àkíyèsí oná tí ó ń gbà siṣe.
Oro ẹnu akowé ìlera Eko ìgbà kan tí Fádípe gbà síle ní
ọdún (1931) túṣu déle ìkòkò nípa oògùn awàrùnsàn níle Yorùbá.
Ge ge bí ó ti wí:
Medicine is among most tribes associated with magic or juju. But among the Yoruba the separation is almost complete, and there exists a society of native doctors. Anyone may practice medicine among the Yoruba and to a certain extent everyman is his own physician…. The principal remedies are for purgative and fever and some at least efficacious. Many preparations are known for the treatment of gonorrhea.
101
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Ìlò egbòogi ń bẹ láàárín àwọn eyà tó jẹ mo oògùn tó ńíi ṣe pelú emí àìrí tàbí májíìkì. Ṣùgbon ní ti ìran Yorùbá, ìlò tewétegbò fún ìlera ènìyàn hànde yàto sí oògùn àjẹmo emí àìrí tàbí májíìkì nìkan bí ó ṣe je pé àwọn awàrùnsàn ìbíle wà. Gbogbo ènìyàn ni ó fere je dókítà ara re níwon ìgbà tó je pé oníkálúkù ló máa ń wá onà láti tojú ara re nípa ìlò tewétegbò. Pàtàkì nínú àwọn àìsàn tí wọn ń fi tewétegbò kojú ni ìgbẹ àti ibà. Won tún ní oríṣíìríṣìí àpapo tewétegbò fún àìsàn àtosí.
Ohun tí Johnson (2009:144) sọ nípa oògùn ìbíle Yorùbá ni pé
àwọn ènìyàn kan wà tí a le pè ní dókítà gege bí iṣe wọn. Àti pé
àwọn wonyìí ni ẹni àsárépè bi nǹkan/àìsàn òjiìjì bá yọjú. Orúkọ
wọn ni adáhunṣe. Johnson fi kún àlàyé re pé bí ó tile je pé kò sí
ilé ìwòsàn kan pàtó, síbe, àwọn adáhunṣe wonyí ti ṣe àwárí
àwọn tewétegbò kan tí wọn fi ń kojú/kápá àwọn àìsàn bíi ete,
àrùn ọpọlọ, ọgbe inú, abbl. Iṣe tí a fúra pé atótónu òkè yìí ń rán
sí àwùjọ ni pé Olódùmarè tó dá edá ti mo pé àìsàn kan tàbí
ìpèníjà kan lórí ìlera wọn yóó máa wà. Ìdí nìyí tí ó fi dá
oríṣìíríṣìí ewé, egbò àti nǹkan mìíràn sí àyíká ọmọ ènìyàn láti le
wúlò fún ìwòsàn àrùn kan tàbí òmíràn. Ohun tí a rí fàyọ nínú iṣe
àwọn onímo nípa oògùn ìbíle Yorùbá meteeta tí a yewò nínú
pépà yìí ni pé onà méjì pàtàkì ni a le pín oògùn ìbíle Yorùbá sí.
Onà kìn-ín-ní ni oògùn ajẹmo tewétegbò, èyí tí ó je pé gbogbo
ènìyàn ni a fere le pè ni dókítà nígbà tí èkejì je mo oògùn tó níi
ṣe pelú ìmísí Olódùmarè tàbí ìgbàgbo nípa àwọn edà tí Ó dá sí
àyíká ọmọ ènìyàn fún ìlera àti àlàáfìà wọn.
102
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Àgbálọgbábo
Kókó ohun tí a jíròrò lé lórí nínú pépà yìí ni àjọsepo tó yẹ kó wà
láàrin edá ènìyàn àti àwọn edá yòókù ti Olódùmarè jọ dá wọn
po ní àyíkà. Pépà yìí menu ba oríṣìíríìṣìí àwọn nǹkan tí wọn wà
ní àyíká ọmọ ènìyàn bíi igi, odò, òkè /àpáta, abbl gege bí wọn ṣe
wúlò fún ìlera ọmọ ènìyàn. A ṣe àyewò ohun tí àwọn onímo ti
wí nípa àyíká àti bí a ṣe lè tojú àyíká ọmọnìyàn láti lè fún wa ní
ìlera tó péye. Onà ibi tí tewétegbò ti wúlò fún ìlera ọmọ ènìyàn
ni a parí àníyàn pépà yìí sí.
Ó hàn nínú iṣe ìwádìí yìí pé púpo nínú àwọn nǹkan tí
Olódùmarè dá sí àyíká edá bíi odò (omi), igbó kìjikìji, ewéko,
òkè ńláńlá, apáta, ẹranko ìgbe àti tile ló wúlò fún edá ènìyàn.
Bákan náà ni a toka sí àwọn ohun tí ó ń pagidínà àlàáfíà àwọn
edá abemí bíi kíkó ẹja lódò lopo yanturu fún títà, pípale rẹpẹtẹ
fún agbo màlúù láti máa sìn fún títà àti opolọpo ariwo gèè. Pépà
yìí wá fi gbèdéke lé e pé níwon ìgbà tó je gbogbo mùtúmùwà ló
mo pé àlàáfìà, ìlera tó péye ni ó ṣe kókó jù lọ nínú ìse mí ayé
ènìyàn, ó yẹ kí tolórí tẹlemù gbìyànjú àti máa tojú àyíká wọn ní
gbogbo ìgbà. Kí won máa gbé ní àyíkà tó mo tónítóní. Bákan
náà kí won má ṣe gé igi lule láìní ìdí. Bee ni dídí onà mọ
odò/omi pelú kíko ilè sí ojú odò kù díe káàtó.
Ìwé Ìtokasí
Abimbọla, W. (1976) Ifa: An Exposition of Ifa Literary Corpus. Ibadan: Oxford University Press.
Adebọwale, B. (2012) Reincaination in Plato and Yoruba Traditional Belief Ninu Yorùbá: Journal of Yoruba
103
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Studies Association of Nigeria. Vol. 7. No.1. Ibadan: Hakolad Prints.
Adeoye, C. (2005). Àsà àti Ìṣe Yorùbá, Ìbàdàn: University Press.
Ajibade, G. ati Raji, S. (2011) Ìsowolo-èdè Àlàbí Ògúndépò, Apá kìníní. Akure: Masterprint Publishers.
Ajuwọn, B. (1981). Ìrèmòjé Eré Ìsípá Ọde. Ìbàdàn: University Press Ltd.
Amoo, A. (1989). Àròfò Òkú Pípè. Ìbàdàn: Longman Plc.
Armitage, D. (2002). Social Institution Dynamics and Political Ecology of Mangrove Forest Conservation in Central Sulawesi; Indonesia: Global Environmental change.
Ayantayọ, J. (2009). Fundamental of Religious Ethics. Ibadan: End-time Publishing House.
Babayemi, S. O. (1980). Egúngún Among the Oyo Yorùbá. Ibadan: Board Publication Ltd.
Bamgbose, A. (2007). The Novels of D.O Fagunwa: A Commentary. Ibadan: Nelson Publishers Ltd.
Daily Trust Editorial (2015). Controlling Noise Pollution. Abuja: Daily Trust Ltd.
Daily Trust Editorial (2015). Household Dust Harbours Thousands of Microbial Species. Abuja: Daily Trust Ltd.
National Planning Commission of Nigeria (2005) National Economic Empowerment and Developmental Strategies (NEEDS). Abuja: b3 Communication Ltd.
Bunza, M.U (2007) Girmace Shrine Among the Dakarkari in Zuruland: An Examination of AfricanTraditional Religion
104
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
in North-Western Nigeria KADA; Journal of Liberal Arts, Vol. 1.No 1. Kaduna State University, Kaduna.
Fadipe, N. A. (1970). The Sociology of the Yoruba. Ibadan: University Press.
Fagunwa, D. O. (1938). Ogboju Ode Ninu Igbo Irunmole. Ibadan: Nelson publishers Ltd.
Fatokun, S. A. (2005). Afican Traditional Religion and Belief Systems ninu Ajayi, S.A. (ed) African Culture and Civilization. Ibadan: Atlantis Books.
Feghabo, C. (2014). Alienation and Ecoactivicism in Selected Works on the Niger-Delta. Unpublished Ph.D Thesis, English Department, University of Ibadan.
Fearnside, P.M. (1993). Deforestation in Brazillian Amazonia: The effect of population and land Tenure. AMB10: A Journal of the Human Environment, 22, 8, 537-545.
Glaser, M. (2006). The Social Dimension in Eco-system Management: Strengthens and Weaknesses of Human Nature Mind Map. Centre for Human Marine Econology (ZMT). Germany: University of Breven Press.
Hultric, M.; C. Folke and N. Kantsky (2002). Development and Government Policies of the Shrimp Farming Industry in Thailand in Relation to Mangrove Ecossytems. Ecological Economics, 40, 3441-455.
Hultric, M. (2005). Lobster and Couch Fisheries of Belize: A Historical Sequencial Exploitation. Ecology and Society 10,1,21.
Idowu, B. (1996) Olodumare: God in Yoruba Belief. Ikeja: Longman Nigeria, PLC.
105
Ètò Ìlera Ajẹmáyìíká: Àyewò Ènìyàn Àti Àwọn Edá Abemí Mìíràn
Ilesanmi, M. (2014). Obìnrin: A Cultural Assessment of Yoruba Women. Ile-ife: Astra Multimedia.
Isola, A. (2010). Making Culture Memorable: Essays on Language, Culture and Development. Ibadan: DB. Martoy Books, and Hope Publications Ltd.
Isola, A. (1990). Ogún Ọmọdè. Ibadan: University Press.
Johnson, S. (2009). The History of the Yoruba: Lagos: CSS Books Ltd.
Obed, A. (2001). Antelop (Woman) and Buffalo (Woman): Contemporary Literary Transformation of a Topos in Yoruba Culture. A Thesis submitted to the School of Oriental and African Studies, University of London.
Olayemi, V. (1975). The Supernatural in the Yoruba Folktales ninu Abimbola, W. (ed) Yoruba Oral Tradition: Poetry, Music, Dance and Drama. Ibadan: Ibadan University Press.
Oluponna, J.K. (2011). City of 201 Gods: Ile-ife in Time, Space and Imagination. London: University of California Press.
Opefeyitimi, A. (1997). Tíorì àti Ìsọwolo-Èdè. Ilé-ife: Obafemi Awolowo University Press.
Oyelaran, (2011). Written in Flames: A Tale of an Environment in Peril: An Inaugural Lecture delivered at the Univeristy of Ibadan.
Santangelo, B. (2007). Different Shades of Green: Ecocriticism and African Literature ninu Olaniyan, T.and Quayson, A. (ed) African Literature, An Anthology of Criticism and Theory. UK: Blackwell Publishing.
106
Yorùbá: Journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria (Vol. 8 No. 2)
Slaymaker, W. (2007). Echoing the Other(s): The Call of Global Green and Black African Responses Ninu Olaniyan, T and Quayson, A. (ed) African Literature, An Anthology of Criticism and Theory. UK: Blackwell Publishing.